Isaiah 1:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA ní, “Kí ni gbogbo ẹbọ yín jámọ́ fún mi? Àgbò tí ẹ fi ń rú ẹbọ sísun sí mi ti tó gẹ́ẹ́; bẹ́ẹ̀ náà sì ni ọ̀rá ẹran àbọ́pa. N kò ní inú dídùn sí ẹ̀jẹ̀ mààlúù tabi ti ọ̀dọ́ aguntan tabi ti òbúkọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oluwa ni, kini ọ̀pọlọpọ ẹbọ nyin jasi fun mi? emi kún fun ọrẹ sisun agbò, ati fun ọrá ẹran abọ́pa; bẹ̃ni emi kò si ni inu didùn si ẹjẹ akọ malũ, tabi si ti ọdọ-agutan, tabi si ti obúkọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ọpọ̀lọpọ̀ ẹbọ yín kín ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹbọ yín jásí fún mi?” ni OLÚWA wí. “Mo ti ní ànító àti àníṣẹ́kù ẹbọ sísun ti àgbò àti ọ̀rá ẹran àbọ́pa, Èmi kò ní inú dídùn nínú ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù, ti àgùntàn àti ti orúkọ.