Isaiah 1:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ lọ kọ́ bí eniyan tí ń ṣe rere. Ẹ máa ṣe ẹ̀tọ́. Ẹ máa ran ẹni tí ara ń ni lọ́wọ́. Ẹ máa gbìjà aláìníbaba, kí ẹ sì máa gba ẹjọ́ opó rò.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kọ́ lati ṣe rere; wá idajọ, ràn awọn ẹniti a nilara lọwọ, ṣe idajọ alainibaba, gbà ẹjọ opó rò.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
kọ́ láti ṣe rere! Wá ìdájọ́ òtítọ́, tù àwọn tí a ń pọ́n lójú nínú. Ṣàtìlẹ́yìn fún ẹ̀tọ́ aláìní baba, gbà ẹjọ́ opó rò.