Isaiah 1:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Máa gbọ́, ìwọ ọ̀run, sì fetí sílẹ̀, ìwọ ayé Nítorí pé OLUWA ń sọ̀rọ̀ Ó ní, “Lẹ́yìn tí mo bọ́ àwọn ọmọ, tí mo tọ́ wọn dàgbà tán, ọ̀tẹ̀ ni wọ́n dì sí mi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gbọ́, ẹnyin ọrun, si fi eti silẹ, iwọ aiye: nitori Oluwa ti sọ̀rọ, emi ti bọ́, emi si ti tọ́ awọn ọmọ, nwọn si ti ṣọ̀tẹ si mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbọ́ ẹ̀yin ọ̀run! Fi etí sílẹ̀, ìwọ ayé! Nítorí OLÚWA ti sọrọ̀: “Mo tọ́ àwọn ọmọ dàgbà, Ṣùgbọ́n wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi.