Isaiah 1:24 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí náà, OLUWA àwọn ọmọ ogun, Alágbára Israẹli ní: “N óo bínú sí àwọn ọ̀tá mi, n óo sì gbẹ̀san lára àwọn tí ó kórìíra mi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina Oluwa, Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ẹni alagbara Israeli, wipe, A, emi o fi aiya balẹ niti awọn ọtá mi, emi o si gbẹ̀san lara awọn ọtá mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà ni OLÚWA, OLÚWA àwọn ọmọ-ogun Alágbára kanṣoṣo tí Ísírẹ́lì sọ wí pé: “Á à! Èmi yóò ní ìfọ̀kànbalẹ̀ lórí àwọn ọ̀tá mi n ó sì gbẹ̀ṣan lára àwọn ọ̀tá mi.