Isaiah 1:31 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Alágbára yóo dàbí ògùṣọ̀, iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ bí ìṣáná. Àwọn mejeeji ni yóo jóná pọ̀, kò sì ní sí ẹni tí yóo lè pa iná náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Alagbara yio si dabi ògùṣọ̀, iṣẹ rẹ̀ yio si dabi ẹta-iná, ati awọn mejeji yio jọ jona pọ̀, ẹnikẹni kì yio si pa wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Alágbára ọkùnrin náà yóò sì dàbí lẹ́ù iṣẹ́ rẹ̀ bí ẹ̀ṣẹ́-iná, àwọn méjèèjì ni yóò jóná papọ̀, láì sí ẹni tí yóò lè pa iná yìí.”