Isaiah 1:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Láti àtẹ́lẹsẹ̀ dé orí yín, kò síbìkan tí ó gbádùn. Gbogbo ara yín kún fún ọgbẹ́ ati egbò tí ń ṣẹ̀jẹ̀. Ẹnikẹ́ni kò wẹ egbò yín, wọn kò dì wọ́n, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò fi òògùn sí wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Lati atẹlẹ̀sẹ titi fi de ori kò si ilera ninu rẹ̀; bikòṣe ọgbẹ́, ipalara, ati õju ti nrà: nwọn kò iti pajumọ, bẹ̃ni a kò iti dì wọn, bẹ̃ni a kò si ti ifi ororo kùn wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Láti àtẹ́lẹṣẹ̀ yín dé àtàrí yín kò sí àlàáfíà rárá, àyàfi ọgbẹ́ òun ìfarapa àti ojú egbò, tí a kò nùnù tàbí kí á dì tàbí kí a kùn ún ní òróró.