Isaiah 10:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí ó ní, “Agbára mi ni mo fi ṣe èyí, ọgbọ́n mi ni mo fi ṣe é nítorí pé mo jẹ́ amòye. Mo yí ààlà àwọn orílẹ̀-èdè pada, mo kó ẹrù tí ó wà ninu ilé ìṣúra wọn. Mo ré àwọn tí wọ́n jókòó lórí ìtẹ́ bọ́ sílẹ̀ bí alágbára ọkunrin.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori o wipe, nipa agbara ọwọ́ mi ni emi ti ṣe e, ati nipa ọgbọ́n mi; nitori emi moye, emi si ti mu àla awọn enia kuro, emi si ti ji iṣura wọn, emi si ti sọ awọn ará ilu na kalẹ bi alagbara ọkunrin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí ó sọ pé: “ ‘Pẹ̀lú agbára ọwọ́ọ̀ mi ni mo fi ṣe èyí àti pẹ̀lú ọgbọ́n ọ̀n mi, nítorí mo ní òye. Mo mú ààlà àwọn orílẹ̀ èdè kúrò, Mo sì ti kó ìṣúra wọn. Gẹ́gẹ́ bí alágbára kan, mo borí àwọn ọba wọn.