Isaiah 10:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Mo nawọ́ kó ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè, bí ẹni nawọ́ kó ọmọ ẹyẹ. Mo kó gbogbo ayé, bí ẹni kó ẹyin ẹyẹ tí ó kọ ẹyin rẹ̀ sílẹ̀, tí ó fò lọ, kò sí ẹnìkan tí ó lè ṣe nǹkankan, kò sí ẹnìkan tí ó lanu sọ̀rọ̀, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò gbin.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọwọ́ mi si ti wá ọrọ̀ awọn enia ri bi itẹ ẹiyẹ: ati gẹgẹ bi ẹnipe ẹnikan nko ẹyin ti o kù, li emi ti kó gbogbo aiye jọ; kò si ẹniti o gbọ̀n iyẹ, tabi ti o ya ẹnu, tabi ti o dún.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ènìyàn tií tọwọ́ bọ ìtẹ́ ẹyẹ, bẹ́ẹ̀ ni ọwọ́ọ̀ mi tẹ ọrọ̀ àwọn orílẹ̀ èdè. Bí ènìyàn tii kó ẹyin tí a kọ̀ sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni mo kó àwọn orílẹ̀ èdè kò sí èyí tí ó fapálupá, tàbí kí ó ya ẹnu láti dún.’ ”