Isaiah 10:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí náà, OLUWA àwọn ọmọ ogun yóo rán àìsàn apanirun sí ààrin àwọn akọni ọmọ ogun rẹ̀. Dípò ohun tí wọ́n fi ń ṣe ògo, ajónirun yóo jó wọn bí ìgbà tí iná bá jóni.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina ni Oluwa, Oluwa awọn ọmọ-ogun yio mu awọn tirẹ̀ ti o sanra di rirù: ati labẹ ogo rẹ̀ yio da jijo kan bi jijo iná.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà, ni OLÚWA, OLÚWA àwọn ọmọ-ogun, yóò rán àrùn ìrẹ̀dànù sórí àwọn akíkanjú jagunjagun, lábẹ́ ògo rẹ̀ ni iná kan yóò ti sọ gẹ́gẹ́ bí iná ajónirun.