Isaiah 10:24 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí náà OLUWA, OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “Ẹ̀yin eniyan mi tí ń gbé Sioni, Ẹ má bẹ̀rù àwọn ará Asiria bí wọn bá fi ọ̀gọ lù yín, tabi tí wọn gbé ọ̀pá sókè si yín bí àwọn ará Ijipti ti ṣe si yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina bayi li Oluwa, Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, Ẹnyin enia mi ti ngbe Sioni, ẹ má bẹ̀ru awọn ara Assiria: on o fi ọgọ lù ọ, yio si gbe ọpa rẹ̀ soke si ọ, gẹgẹ bi iru ti Egipti.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà, báyìí ni OLÚWA, OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí, “Ẹ̀yin ènìyàn mi tí ó ń gbé Ṣíhónì, Ẹ má ṣe bẹ̀rù àwọn Ásíríà, tí ó ń fi ọ̀pá lù yín, tí wọ́n sì ń gbé ọ̀gọ tìyín bí Éjíbítì ti ṣe.