Isaiah 10:26 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Èmi, OLUWA àwọn ọmọ ogun, n óo fi ọ̀pá mi nà wọ́n, bí ìgbà tí mo na àwọn ará Midiani ní ibi àpáta Orebu. Ọ̀pá rẹ̀ yóo wà lórí òkun. Yóo tún gbé e sókè bí ó ti ṣe ní Ijipti.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oluwa awọn ọmọ-ogun yio gbe paṣan kan soke fun u, gẹgẹ bi ipakupa ti Midiani ni apata Orebu: ati gẹgẹ bi ọgọ rẹ̀ soju okun, bẹ̃ni yio gbe e soke gẹgẹ bi iru ti Egipti.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA àwọn ọmọ-ogun yóò nà wọ́n ní ẹgba. Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe lu Mídíánì ní òkè Órébù, yóò sì gbé ọ̀páa rẹ̀ lé orí omi gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ní Éjíbítì.