Isaiah 10:33 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ wò ó! OLUWA, OLUWA àwọn ọmọ ogun, yóo gé àwọn ẹ̀ka igi náà pẹlu agbára tí ó bani lẹ́rù. Yóo gé àwọn tí ó ga fíofío lulẹ̀, yóo sì rẹ àwọn agbéraga sílẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kiyesi i, Oluwa, Oluwa awọn ọmọ-ogun yio fi ẹ̀ru wọ́n ẹka: ati awọn ti o ga ni inà li a o ke kuro, ati awọn agberaga li a o rẹ̀ silẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wò ó, OLÚWA, OLÚWA àwọn ọmọ-ogun, yóò kán ẹ̀ka náà sọnù pẹ̀lú agbára. Àwọn igi ọlọ́lá ni a ó gé lulẹ̀ Àwọn tí ó ga gogoro ni a ó rẹ̀ sílẹ̀.