Isaiah 10:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Kò sí ohun tí ó kù àfi kí ẹ kú lójú ogun, tabi kí ẹ ká góńgó láàrin àwọn tí wọ́n kó lẹ́rú. Sibẹsibẹ inú OLUWA kò ní rọ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò ní dá ọwọ́ ìjà rẹ̀ dúró.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Laisi emi nwọn o tẹ̀ ba labẹ awọn ara-tubu, nwọn o si ṣubu labẹ awọn ti a pa. Ni gbogbo eyi ibinu rẹ̀ kò yi kuro, ṣugbọn ọwọ́ rẹ̀ nà jade sibẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ohunkóhun kò ní ṣẹ́kù mọ́ bí kò ṣe láti tẹ̀ ba láàrin àwọn ìgbèkùn tàbí kí o ṣubú sáàrin àwọn tí a pa. Pẹ̀lú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, ìbínú rẹ̀ kò kúrò, ọwọ́ rẹ̀ sì tún gbé sókè.