Isaiah 10:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Mo rán wọn láti gbógun ti àwọn tí kò mọ Ọlọrun, ati àwọn eniyan tí wọ́n bá mú mi bínú. Pé kí wọ́n kó wọn lẹ́rù. Kí wọ́n kó wọn lẹ́rú kí wọ́n tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ bíi ẹrọ̀fọ̀ tí à ń tẹ̀ mọ́lẹ̀ níta gbangba.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o ran a si orilẹ-ède agabàgebe, ati fun awọn enia ibinu mi li emi o paṣẹ kan, lati ko ikogun, ati lati mu ohun ọdẹ, ati lati tẹ̀ wọn mọlẹ bi ẹrẹ̀ ni igboro.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mo rán an sí orílẹ̀ èdè aláìní Ọlọ́run Mo dojúu rẹ̀ kọ àwọn ènìyàn tí ó múmi bínú láti já ẹrù gbà, àti láti kó ìkógun láti tẹ̀mọ́lẹ̀ bí amọ̀ ní ojú òpópó.