Isaiah 11:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ní ọjọ́ náà, gbòǹgbò Jese yóo dúró bí àsíá fún àwọn orílẹ̀-èdè, òun ni àwọn orílẹ̀-èdè yóo máa wá. Ibùgbé rẹ̀ yóo jẹ́ èyí tí ó lógo.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati li ọjọ na kùkute Jesse kan yio wà, ti yio duro fun ọpágun awọn enia; on li awọn keferi yio wá ri: isimi rẹ̀ yio si li ogo.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọjọ́ náà, gbòǹgbò Jéésè yóò dúró gẹ́gẹ́ bí àṣíá fún gbogbo ènìyàn, àwọn orílẹ̀ èdè yóò pagbo yí i ká, ibùdó ìsinmi rẹ̀ yóò jẹ́ èyí tí ó lógo.