Isaiah 11:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Yóo gbé àsíá sókè fún àwọn orílẹ̀-èdè, yóo kó àwọn Israẹli tí a ti patì jọ. Yóo ṣa àwọn ọmọ Juda tí wọ́n fọ́nká jọ, láti orígun mẹrẹẹrin ilẹ̀ ayé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
On o si gbe ọpagun kan duro fun awọn orilẹ-ède, yio si gbá awọn aṣati Israeli jọ, yio si kó awọn ti a tuka ni Juda jọ lati igun mẹrin aiye wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Òun yóò gbé àṣíá sókè fún àwọn orílẹ̀ èdè, yóò sì kó àwọn ìgbèkùn Ísírẹ́lì jọ, yóò kó gbogbo àwọn ènìyàn Júdà tí a ti fọ́n káàkiri jọ, láti igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ ayé.