Isaiah 11:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọn óo kọlu àwọn ará Filistini ní ìhà ìwọ̀ oòrùn, wọn yóo jọ ṣẹgun àwọn ará ìlà oòrùn. Wọn yóo sì jọ dojú ìjà kọ Edomu ati Moabu. Àwọn ará Amoni yóo gbọ́ràn sí wọn lẹ́nu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn nwọn o si fò mọ ejika awọn Filistini siha iwọ̀-õrun; nwọn o jùmọ bà awọn ti ilà-õrun jẹ: nwọn o si gbe ọwọ́ le Edomu ati Moabu; awọn ọmọ Ammoni yio si gbà wọn gbọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọn yóò dìgbòlu àwọn gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Fílísítíà ni apá ìwọ̀ oòrùn, wọn yóò pawọ́pọ̀ kọlu àwọn ènìyàn apá ìlà oòrùn. Wọn yóò gbé ọwọ́ọ wọn lé Édómù àti Móábù, àwọn ará Ámónì yóò sì di ìwẹ̀fàa wọn.