Isaiah 11:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ọ̀nà tí ó gbòòrò yóo wà láti Asiria, fún ìyókù àwọn eniyan rẹ̀; bí ó ti ṣe wà fún àwọn ọmọ Israẹli, nígbà tí wọn ń bọ̀ láti Ijipti.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọna opopo kan yio si wà fun iyokù awọn enia rẹ̀, ti yio kù, lati Assiria; gẹgẹ bi o ti ri fun Israeli li ọjọ ti o goke jade kuro ni ilẹ Egipti.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọ̀nà gidi yóò wà fún àwọn ènìyàn an rẹ̀ tí ó ṣẹ́kù tí ó kù sílẹ̀ ní Ásíríà, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà fún Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n gòkè láti Éjíbítì wá.