Isaiah 11:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn yóo fi òdodo ṣe ìdájọ́ àwọn talaka, yóo fi ẹ̀tọ́ gbèjà àwọn onírẹ̀lẹ̀, yóo fi ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ na ayé bíi pàṣán, yóo sì fi èémí ẹnu rẹ̀ pa àwọn oníṣẹ́ ibi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn yio fi ododo ṣe idajọ talakà, yio si fi otitọ ṣe idajọ fun awọn ọlọkàn tutù aiye; on o si fi ọgọ ẹnu rẹ̀ lu aiye, on o si fi ẽmi ète rẹ̀ lu awọn enia buburu pa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n pẹ̀lú òdodo ni yóò ṣe ìdájọ́ àwọn aláìní, pẹ̀lú òtítọ́ ni yóò ṣe ìpinnu fún àwọn aláìní ayé. Òun yóò lu ayé pẹ̀lú ọ̀pá tí ó wà ní ẹnu rẹ̀, pẹ̀lú ooru ẹnu rẹ̀ ni yóò pa àwọn ìkà.