Isaiah 12:2 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wò ó! Ọlọrun ni olùgbàlà mi, n óo gbẹ́kẹ̀lé e ẹ̀rù kò sì ní bà mí, nítorí pé OLUWA Ọlọrun ni agbára mi, ati orin mi, òun sì ni Olùgbàlà mi.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kiyesi i, Ọlọrun ni igbala mi; emi o gbẹkẹle, emi ki yio si bẹ̀ru: nitori Oluwa Jehofah li agbara mi ati orin mi; on pẹlu si di igbala mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítòótọ́ Ọlọ́run ni ìgbàlà mi, Èmi yóò gbẹ́kẹ̀lé e èmi kì yóò bẹ̀rù. OLÚWA, OLÚWA náà ni agbára à mi àti orin ìn mi, òun ti di ìgbàlà mi.”