Isaiah 12:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ óo sọ ní ọjọ́ náà pé, “Ẹ fọpẹ́ fún OLUWA, ẹ ké pe orúkọ rẹ̀, ẹ kéde iṣẹ́ rere rẹ̀ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè; ẹ kéde pé a gbé orúkọ rẹ̀ ga.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Li ọjọ na li ẹnyin o si wipe, Yìn Oluwa, kepe orukọ rẹ̀, sọ iṣẹ́ rẹ̀ lãrin awọn enia, mu u wá si iranti pe, orukọ rẹ̀ li a gbe leke.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọjọ́ náà, ìwọ yóò wí pé: “Fi ọpẹ́ fún OLÚWA, ké pe orúkọ rẹ̀, Jẹ́ kí ó di mímọ̀ láàrin àwọn orílẹ̀ èdè, ohun tí ó ti ṣe kí o sì kéde pé a ti gbé orúkọ rẹ̀ ga.