Isaiah 13:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí àgbájọpọ̀ àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run yóo kọ̀, wọn kò ní tan ìmọ́lẹ̀. Oòrùn yóo ṣókùnkùn nígbà tí ó bá yọ, òṣùpá kò sì ní tan ìmọ́lẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori awọn iràwọ ọrun, ati iṣùpọ iràwọ inu rẹ̀ kì yio tàn imọlẹ wọn: õrun yio ṣu okùnkun ni ijadelọ rẹ̀, oṣùpa kì yio si mu ki imọlẹ rẹ̀ tàn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run ati ìkójọpọ̀ wọn kò sì ní fi ìmọ́lẹ̀ wọn hàn. Àṣẹ̀ṣẹ̀yọ òòrùn yóò di òkùnkùn àti òṣùpá kò ní fi ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ hàn.