Isaiah 13:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
N óo fìyà jẹ ayé nítorí iṣẹ́ ibi rẹ̀, n óo sì jẹ àwọn ìkà níyà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. N óo fòpin sí àṣejù àwọn onigbeeraga, n óo rẹ ìgbéraga àwọn tí kò lójú àánú sílẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o si bẹ̀ ibi wò lara aiye, ati aiṣedẽde lara awọn enia buburu; emi o si mu ki igberaga awọn agberaga ki o mọ, emi o si mu igberaga awọn alagbara rẹ̀ silẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi yóò jẹ ayé ní ìyà nítorí ibi rẹ̀, àwọn ìkà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ẹ wọn. Èmi yóò fi òpin sí gààrù àwọn agbéraga èmi ó sì rẹ ìgbéraga àwọn aláìláàánú sílẹ̀.