Isaiah 13:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọn yóo fi ọfà pa àwọn ọdọmọkunrin, wọn kò ní ṣàánú oyún inú, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní ṣàánú àwọn ọmọde.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọrun wọn pẹlu yio fọ́ awọn ọdọmọkunrin tũtũ; nwọn ki yio ṣãnu fun ọmọ-inu: oju wọn kì yio dá ọmọde si.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọrùn wọn yóò ré àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin lulẹ̀; wọn kò ní ṣàánú àwọn mọ̀jèsín tàbí kí wọn síjú àánú wo àwọn ọmọdé.