Isaiah 13:19 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Babiloni, ìwọ tí o lógo jù láàrin gbogbo ìjọba ayé, ìwọ tí o jẹ́ ẹwà ati ògo àwọn ará Kalidea, yóo dàbí Sodomu ati Gomora, nígbà tí Ọlọrun pa wọ́n run.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati Babiloni, ogo ijọba gbogbo, ẹwà ogo Kaldea, yio dabi igbati Ọlọrun bi Sodomu on Gomorra ṣubu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bábílónì, ohun ọ̀ṣọ́ àwọn ìjọba ògo ìgbéraga àwọn ará Bábílónì ni Ọlọ́run yóò dojúrẹ̀ bolẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Sódómù àti Gòmórà.