Isaiah 13:21 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn àwọn ẹranko ní yóo máa sùn níbẹ̀ ilé rẹ̀ yóo sì kún fún ẹyẹ òwìwí, ògòǹgò yóo máa gbè ibẹ̀ ẹhànnà òbúkọ yóo sì máa ta pọ́núnpọ́nún káàkiri ibẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn ẹranko igbẹ yio dubulẹ nibẹ; ile wọn yio si kun fun òwiwí, abo ogòngo yio ma gbe ibẹ, ọ̀rọ̀ yio si ma jo nibẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n àwọn ohun abẹ̀mí aṣálẹ̀ ni yóò gbé bẹ̀, àwọn ajáko yóò kún inú ilé wọn, níbẹ̀ ni àwọn òwììwí yóò máa gbé níbẹ̀ ni àwọn ewúrẹ́-igbó yóò ti máa bẹ́ kiri.