Isaiah 13:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Gbọ́ ariwo lórí òkè, bí ohùn ọ̀pọ̀ eniyan, gbọ́ ariwo ìdàrúdàpọ̀ ìjọba àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ń péjọ pọ̀! OLUWA àwọn ọmọ ogun ní ń kó àwọn ọmọ ogun jọ fún ogun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ariwo ọ̀pọlọpọ lori oke, gẹgẹ bi ti enia pupọ̀: ariwo rudurudu ti ijọba awọn orilẹ-ède, ti a kojọ pọ̀: Oluwa awọn ọmọ-ogun gbá ogun awọn ọmọ-ogun jọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbọ́ ohùn kan ní àwọn orí òkè, gẹ́gẹ́ bí i ti ogunlọ́gọ̀ ènìyàn Gbọ́, ìdàrúdàpọ̀ láàrin àwọn ìjọba, gẹ́gẹ́ bí i ti ìkórajọ àwọn orílẹ̀ èdè! OLÚWA àwọn ọmọ-ogun ti kó ogun rẹ̀ jọ àwọn jagunjagun fún ogun.