Isaiah 13:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
ẹnu yóo sì yà wọ́n. Ìpayà ati ìrora yóo mú wọn, wọn yóo wà ninu ìrora bí obinrin tí ó ń rọbí; wọn óo wo ara wọn tìyanu-tìyanu, ojú yóo sì tì wọ́n.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn o si bẹ̀ru: irora ati ikãnu yio dì wọn mu; nwọn o wà ni irora bi obinrin ti nrọbi: ẹnu yio yà ẹnikan si ẹnikeji rẹ̀; oju wọn yio dabi ọwọ́-iná.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ̀rù yóò gbá wọn mú, ìrora àti ìpayínkeke yóò dì wọ́n mú, wọn yóò kérora gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó ń rọbí. Ẹnìkín-ín-ní yóò wo ẹnìkejìi rẹ̀ pẹ̀lú ìpayà ojú wọn á sìgbinájẹ.