Isaiah 14:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA yóo ṣíjú àánú wo Jakọbu yóo tún yan Israẹli, yóo sì fi wọ́n sórí ilẹ̀ wọn. Àwọn àlejò yóo darapọ̀ mọ́ wọn, wọn yóo sì di ọ̀kan náà pẹlu ilé Jakọbu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
NITORI Oluwa yio ṣãnu fun Jakobu, yio si tun yan Israeli, yio si mu wọn gbe ilẹ wọn; alejò yio si dapọ̀ mọ wọn, nwọn o si faramọ ile Jakobu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA yóò fi àánú hàn fún Jákọ́bù, yóò tún Ísírẹ́lì yàn lẹ́ẹ̀kan síi yóò sì fi ìdíi wọn kalẹ̀ ní ilẹ̀ àwọn tìkálára wọn. Àwọn àjèjì yóò darapọ̀ mọ́ wọn, wọn yóò sì fọwọ́ṣowọ́pọ̀ pẹ̀lú ilée Jákọ́bù.