Isaiah 14:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó pinnu lọ́kàn ara rẹ̀ pé, ‘N óo gòkè dé ọ̀run, n óo gbé ìtẹ́ mi kọjá àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run; n óo jókòó lórí òkè àpéjọ àwọn eniyan, ní ìhà àríwá ní ọ̀nà jíjìn réré.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori iwọ ti wi li ọkàn rẹ pe, Emi o goke lọ si ọrun, emi o gbe itẹ mi ga kọja iràwọ Ọlọrun: emi o si joko lori oke ijọ enia ni iha ariwa:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìwọ sọ nínú ọkàn rẹ pé, “Èmi yóò gòkè lọ sí ọ̀run; Èmi yóò gbé ìtẹ́ mi sókè ga ju àwọn ìràwọ̀ Ọlọ́run, Èmi yóò gúnwà ní orí òkè àpèjọ ní ṣónṣó orí òkè mímọ́.