Isaiah 14:19 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn a lé ìwọ kúrò ninu ibojì rẹ, bí ọmọ tí a bí kí oṣù rẹ̀ tó pé, tí a gbé òkú rẹ̀ sọnù; tí a jù sáàrin òkú àwọn jagunjagun tí a pa lójú ogun; àwọn tí a jù sinu kòtò olókùúta, bí àwọn tí a tẹ̀ ní àtẹ̀pa.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn iwọ li a gbe sọnù kuro nibi iboji rẹ bi ẹka irira, bi aṣọ awọn ti a pa, awọn ti a fi idà gun li agunyọ, ti nsọkalẹ lọ si ihò okuta; bi okú ti a tẹ̀ mọlẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n a jù ọ́ síta kúrò nínú ibojì gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ka igi tí a kọ̀ sílẹ̀, àwọn tí a pa ni ó bò ọ́ mọ́lẹ̀, àwọn tí idà ti gún, àwọn tí ó ṣọ̀kalẹ̀ lọ sínú òkúta inú ọ̀gbun. Gẹ́gẹ́ bí òkú ó di ìtẹ̀mọ́lẹ̀ ní abẹ́ àtẹ́lẹṣẹ̀,