Isaiah 14:20 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
A kò ní sin ọ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn ọba yòókù, nítorí pé o ti pa ilẹ̀ rẹ run, o sì ti pa àwọn eniyan rẹ. Kí á má dárúkọ àwọn ìran ẹni ibi mọ́ títí lae!
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
A kì o sin ọ pọ̀ pẹlu wọn, nitoriti iwọ ti pa ilẹ rẹ run, o si ti pa awọn enia rẹ: iru awọn oluṣe buburu li a kì o darukọ lailai.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
A kò ní sin ọ́ pẹ̀lúu wọn, nítorí pé o ti ba ilẹ̀ rẹ jẹ́ o sì ti pa àwọn ènìyàn rẹ. Ìran àwọn ìkà ni a kì yóò dárúkọ wọn mọ́.