Isaiah 14:22 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “N óo gbógun tì wọ́n, n óo pa orúkọ Babiloni rẹ́ ati ìyókù àwọn eniyan tí ó wà ninu rẹ̀, ati arọmọdọmọ wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori emi o dide si wọn, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; emi o si ke orukọ ati iyokù kuro ni Babiloni, ati ọmọ, ati ọmọ de ọmọ, ni Oluwa wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Èmi yóò dìde ṣókè sí wọn,” ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí. “Èmi yóò ké orúkọ rẹ̀ kúrò ní Bábílónì àti àwọn tí ó sálà, àwọn ọmọ àti ìran rẹ̀,” ni OLÚWA wí.