Isaiah 14:29 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Gbogbo ẹ̀yin ará Filistini, ẹ má yọ̀ pé a ti ṣẹ́ ọ̀pá tí ó lù yín; nítorí pé paramọ́lẹ̀ ni yóo yọ jáde láti inú àgékù ejò, ejò tí ń fò sì ni ọmọ rẹ̀ yóo yà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ máṣe yọ̀, gbogbo Filistia, nitori paṣan ẹniti o nà ọ ṣẹ́; nitori lati inu gbòngbo ejo ni pãmọlẹ kan yio jade wá, irú rẹ̀ yio si jẹ́ ejò iná ti nfò.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Má ṣe yọ̀, gbogbo ẹ̀yin Fílístínì, pé ọ̀pá tí ó lù ọ́ ti dá; láti ibi gbòngbò ejò náà ni pamọ́lẹ̀ yóò ti hù jáde, èṣo rẹ̀ yóò sì jẹ́ oró ejò tíí jóni.