Isaiah 14:30 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àkọ́bí talaka yóo rí oúnjẹ jẹ, aláìní yóo sì dùbúlẹ̀ láì léwu. Ṣugbọn n óo fi ìyàn pa àwọn ọmọ ilẹ̀ rẹ, a óo sì fi idà pa àwọn tó kù ní ilẹ̀ rẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Akọbi awọn otòṣi yio si jẹ, awọn alaini yio si dubulẹ lailewu; emi o si fi iyàn pa gbòngbo rẹ, on o si pa iyokù rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹni tí ó kúṣẹ̀ẹ́ jù yóò ní pápá oko, àwọn aláìní yóò sì dùbúlẹ̀ láìléwu. Ṣùgbọ́n gbòǹgbòo rẹ ni èmi ó fi ìyàn parun, yóò sì ké àwọn ẹni rẹ tí ó sálà kúrò.