Isaiah 14:31 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Máa sọkún, ìwọ ẹnubodè, kí ìwọ ìlú sì figbe ta. Ẹ̀yin ará Filistini, ẹ máa gbọ̀n jìnnìjìnnì nítorí pé àwọn ọmọ ogun kan ń rọ́ bọ̀ bí èéfín, láti ìhà àríwá, kò sí ọ̀kan ninu àwọn ọmọ ogun wọn tí ó ń ṣe dìẹ̀dìẹ̀ bọ̀ lẹ́yìn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Hu, iwọ ẹnu-odi; kigbe, iwọ ilu; gbogbo Palestina, iwọ ti di yiyọ́: nitori ẹ̃fin yio ti ariwa jade wá, ẹnikan kì yio si yà ara rẹ̀ kuro lọdọ ẹgbẹ́ rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kígbe, Ìwọ ẹnu ọ̀nà! Pariwo, Ìwọ ìlú! Yọ́ kúrò, gbogbo ẹ̀yin Fílístínì! Kurukuru èéfín kan ti Àríwá wá, kò sì sí amóríbọ́ kan nínú ẹgbẹ́ wọn.