Isaiah 14:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Isà òkú ti lanu sílẹ̀ láti pàdé rẹ bí o bá ti ń dé. Ó ta àwọn òkú ọ̀run jí láti kí ọ, àwọn tí wọ́n ṣe pataki ní àkókò wọn, Ó gbé gbogbo àwọn ọba orílẹ̀-èdè dìde lórí ìtẹ́ wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ipò-okú lati isalẹ wá mì fun ọ lati pade rẹ li àbọ rẹ: o rú awọn okú dide fun ọ, ani gbogbo awọn alakoso aiye; o ti gbe gbogbo ọba awọn orilẹ-ède dide kuro lori itẹ wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ibojì tí ó wà ní ìṣàlẹ̀ ni a ru sókè láti pàdé rẹ ní àpadàbọ̀ rẹ̀ ó ru ẹ̀mí àwọn tí ó ti lọ ṣókè láti wá kí ọ gbogbo àwọn tí ó jẹ́ olórí ní ayé ó mú kí wọn dìde lórí ìtẹ́ẹ wọn gbogbo àwọn tí ó jọba lórí àwọn orílẹ̀ èdè.