Isaiah 15:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ọmọbinrin Diboni ti gun àwọn ibi pẹpẹ tí wọ́n ti ń bọ̀rìṣà lọ, wọ́n lọ sọkún. Moabu ń pohùnréré ẹkún nítorí Nebo ati Medeba. Gbogbo orí wọn pá, wọ́n sì ti fá gbogbo irùngbọ̀n wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
On ti goke lọ si Bajiti, ati si Diboni, ibi giga wọnni, lati sọkun: Moabu yio hu lori Nebo, ati lori Medeba: gbogbo ori wọn ni yio pá, irungbọ̀n olukulùku li a o fá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Díbónì gòkè lọ sí tẹ́ḿpìlìi rẹ̀, sí àwọn ibi gíga rẹ̀ láti ṣunkún, Móábù pohùnréré lórí Nébónì àti Médíbà. Gbogbo orí ni a fá gbogbo irungbọ̀n ni a gé dànù.