Isaiah 15:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n da aṣọ ọ̀fọ̀ bora ní ìta gbangba. Gbogbo wọn dúró lórí òrùlé ilé wọn, ati ní gbogbo gbàgede, wọ́n ń pohùnréré ẹkún, omijé sì ń dà lójú wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ni igboro ni wọn o da aṣọ-ọ̀fọ bò ara wọn: lori okè ilé wọn, ati ni igboro wọn, olukuluku yio hu, yio si ma sọkun pẹ̀rẹpẹ̀rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n wọ aṣọ ọ̀fọ̀ ní ojú òpópónà, ní àwọn òrùlé àti àwọn gbàgede àkójọ wọ́n pohùnréré, Wọ́n dọ̀bálẹ̀ pẹ̀lú ẹkún.