Isaiah 15:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Heṣiboni ati Eleale ń kígbe lóhùn rara, àwọn ará Jahasi gbọ́ ariwo wọn; nítorí náà àwọn ọmọ ogun Moabu sọkún, ọkàn rẹ̀ sì wárìrì.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Heṣboni yio si kigbe, ati Eleale: a o si gbọ́ ohùn wọn titi dé Jahasi: nitorina ni awọn ọmọ-ogun Moabu ti o hamọra yio kigbe soke; ọkàn rẹ̀ yio bajẹ fun ara rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Hẹ́ṣíbónì àti Élíálè ké ṣóde, ohùn wọn ni a gbọ́ títí fi dé Jáhásì. Nítorí náà ni àwọn ọmọ ogun Móábù ṣe kígbe tí ọkàn wọn sì rẹ̀wẹ́sì.