Isaiah 16:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n ti kó ayọ̀ ati ìdùnnú lọ kúrò ninu oko eléso; ẹnikẹ́ni kò kọrin bẹ́ẹ̀ ni kò sí ariwo híhó ninu ọgbà àjàrà wọn. Kò sí àwọn tí ó ń pọn ọtí ninu rẹ̀ mọ́ bẹ́ẹ̀ ni a kò gbọ́ ariwo àwọn tí ń pọn ọtí mọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
A si mu inu-didun kuro, ati ayọ̀ kuro ninu oko ti nso eso ọ̀pọlọpọ; orin kì yio si si mọ ninu ọgbà-àjara, bẹ̃ni kì yio si ihó-ayọ̀ mọ: afọnti kì yio fọn ọti-waini mọ ninu ifọnti wọn, emi ti mu ariwo dá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ayọ̀ àti ìdùnnú ni a ti mú kúrò nínú ọgbà-igi eléso rẹ; kò sí ẹnìkan tí ó kọrin tàbí kígbe nínu ọgbà-àjàrà: ẹnikẹ́ni kò fún ọtí níbi ìfúntí, nítorí mo ti fi òpin sí gbogbo igbe.