Isaiah 16:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn nisinsinyii, OLUWA ní, “Nígbà tí a óo fi rí ọdún mẹta, tíí ṣe iye ọdún alágbàṣe, a óo ti sọ ògo Moabu di ilẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé eniyan inú rẹ̀ pọ̀, àwọn díẹ̀ ni yóo ṣẹ́kù, àárẹ̀ yóo sì ti mú wọn.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn nisisiyi Oluwa ti sọ̀rọ, wipe, Niwọn ọdun mẹta, gẹgẹ bi ọdun alagbaṣe, a o si kẹgàn ogo Moabu, pẹlu gbogbo ọ̀pọlọpọ nì: awọn iyokù yio kere, kì yio si li agbara.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọn ní àkókò yìí OLÚWA wí pé: “Láàrin ọdún mẹ́ta gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀fà tí ó wà lábẹ́ ìdè ọgbà rẹ̀ ti máa kà á, Ògo Móábù àti àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn rẹ̀ ni a ó kẹ́gàn, àwọn tí ó ṣálà nínú un rẹ̀ yóò kéré níye, wọn yóò sì jẹ́ akúrẹtẹ̀.”