Isaiah 16:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Jẹ́ kí àwọn tí a lé jáde ní Moabu, máa gbé ààrin yín. Dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ àwọn apanirun.” Nígbà tí aninilára kò bá sí mọ́ tí ìparun bá dópin, tí atẹnimọ́lẹ̀ bá ti kúrò ní ilẹ̀ náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Moabu, jẹ ki awọn isánsa mi ba ọ gbe, iwọ ma jẹ ãbo fun wọn li oju akoni: nitori alọnilọwọgbà de opin, akoni dasẹ̀, a pa awọn aninilara run kuro lori ilẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jẹ́ kí àwọn ìsáǹsá Móábù gbé pẹ̀lúù rẹ, jẹ́ ààbò fún wọn kúrò lọ́wọ́ ìparun.” Aninilára yóò wá sí òpin, ìparun yóò dáwọ́; òfinràn yóò pòórá kúrò lórí ilẹ̀.