Isaiah 16:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà náà a óo fìdí ìtẹ́ múlẹ̀ pẹlu ìfẹ́ tí kì í yẹ̀. Ẹnìkan tí ń ṣe ìdájọ́ ẹ̀tọ́ ati òdodo yóo jókòó lórí ìtẹ́ náà, Yóo dúró lórí òtítọ́ ní ìdílé Dafidi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ninu ãnu li a o si fi idi ilẹ mulẹ: yio si joko lori rẹ̀ li otitọ ninu agọ Dafidi, yio ma ṣe idajọ, yio si ma wá idajọ, yio si ma mu ododo yara kánkán.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nínú ìfẹ́ a ó fi ìdí ìjọba kan múlẹ̀, ní òdodo ọkùnrin kan yóò jókòó lóríi rẹ̀— ọ̀kan láti ilé Dáfídì wá. Ẹni nní ti ìdájọ́ ń wá ẹ̀tọ́ tí ó sì fi ìyára wá ohun tí í ṣe òdodo.