Isaiah 16:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Gbogbo oko ni ó rọ ní Heṣiboni; bẹ́ẹ̀ náà ni ọgbà Sibuma: àwọn olórí orílẹ̀-èdè ti gé àwọn ẹ̀ka rẹ̀ lulẹ̀, èyí tí ó tàn kálẹ̀ dé Jaseri títí dé inú aṣálẹ̀. Ìtàkùn rẹ̀ tàn kálẹ̀, wọ́n kọjá sí òdìkejì òkun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori igbẹ́ Heṣboni rọ, ati àjara Sibma: awọn oluwa awọn keferi ti ke pataki ọ̀gbin rẹ̀ lu ilẹ, nwọn tàn de Jaseri, nwọn nrìn kakiri aginjù: ẹka rẹ̀ nà jade, nwọn kọja okun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo pápá-oko Héṣíbónì ti gbẹ, bákan náà ni àjàrà Ṣíbínà rí. Àwọn aláṣẹ àwọn orílẹ̀ èdè wọ́n tẹ àwọn àyànfẹ́ àjàrà mọ́lẹ̀, èyí tí ó ti fà dé Jáṣérì ó sì ti tàn dé agbègbè aṣálẹ̀. Àwọn èhu rẹ̀ fọ́n jáde ó sì lọ títí ó fi dé òkun.