Isaiah 16:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí náà mo sọkún fún ọgbà àjàrà Sibuma bí mo ṣe sọkún fún Jaseri; mo sì sọkún nítorí Heṣiboni ati Eleale, mo sọkún, omi ń dà lójú mi pòròpòrò nítorí gbogbo ìkórè yín, ati èso oko yín ni ogun ti kó lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina emi o pohùnrére ẹkun, bi ẹkun Jaseri, àjara Sibma: emi o fi omije mi rin ọ, iwọ Heṣboni, ati Eleale: nitori ariwo nla ta lori èso-igi ẹ̃rùn rẹ, ati lori ikore rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà mo ṣunkún, gẹ́gẹ́ bí Jáṣérì ṣe ṣunkún, fún àwọn àjàrà Ṣíbínà. Ìwọ Hẹ́ṣíbónì, Ìwọ Élíálẹ̀, mo bomirin ọ́ pẹ̀lú omi ojú! Igbe ayọ̀ lórí àwọn èṣo pípọ́n rẹ àti lórí ìkóórè èyí tí o ti mọ́wọ́dúró.