Isaiah 17:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ìró àwọn orílẹ̀-èdè dàbí ti omi òkun ńlá ṣugbọn OLUWA yóo bá wọn wí wọn óo sì sá lọ. Wọn óo dàbí ìràwé tí afẹ́fẹ́ ń gbé lọ lórí òkè, ati bí eruku tí ìjì líle ń fẹ́ kiri.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn orilẹ-ède yio rọ́ bi rirọ́ omi pupọ: ṣugbọn Ọlọrun yio bá wọn wi, nwọn si sa jina rere, a o si lepa wọn gẹgẹ bi ìyangbo oke-nla niwaju ẹfũfu, ati gẹgẹ bi ohun yiyi niwaju ãjà.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ènìyàn ń bú ramúramù gẹ́gẹ́ bí ìrúmi odò, nígbà tí ó bá wọn wí wọ́n ṣálọ jìnnà réré, a tì wọ́n lọ gẹ́gẹ́ bí ìyàngbò ní orí òkè, àti gẹ́gẹ́ bí ewéko níwájú ìjì líle.