Isaiah 17:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àṣàkù yóo kù níbẹ̀, bí ìgbà tí eniyan gbọn igi olifi, yóo ku meji tabi mẹta péré ní góńgó orí igi, tabi bíi mẹrin tabi marun-un lórí ẹ̀ka igi.” OLUWA Ọlọrun Israẹli ló sọ bẹ́ẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn ẽṣẹ́ eso-àjara yio hù ninu rẹ̀, gẹgẹ bi mimì igi olifi, eso kekere meji bi mẹta ni ṣonṣo oke ẹka mẹrin bi marun ni ẹka ode ti o ni eso pupọ, li Oluwa Ọlọrun Israeli wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣíbẹ̀ ṣíbẹ̀ irúgbìn díẹ̀ yóò ṣẹ́kù, gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí a gbọn igi ólífì, tí èṣo ólífì méjì tàbí mẹ́ta ṣẹ́kù sórí ẹ̀ka tí ó ga jùlọ, mẹ́rin tàbí márùn ún lórí ẹ̀ka tí ó so jù,” ni OLÚWA wí, àní Ọlọ́run Ísírẹ́lì.