Isaiah 17:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Tó bá di ìgbà náà, àwọn ìlú olódi ńláńlá wọn yóo dàbí àwọn ìlú tí àwọn ará Hifi ati àwọn ará Amori sá kúrò níbẹ̀, nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli gbógun tì wọ́n; gbogbo rẹ̀ yóo di ahoro.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Li ọjọ na ni ilu alagbara rẹ̀ yio dabi ẹka ìkọsilẹ, ati ẹka tente oke ti nwọn fi silẹ nitori awọn ọmọ Israeli: iparun yio si wà.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọjọ́ náà àwọn ìlú alágbára wọn, tí wọ́n fi sílẹ̀ nítorí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, yóò dàbí ilẹ̀ tí a dà sílẹ̀ kó di ìgbòrò. Gbogbo wọn yóò sì di ahoro.