Isaiah 18:2 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹni tí ó rán ikọ̀ lọ sí òkè odò Naili, tí wọ́n fẹní ṣọkọ̀ ojú omi. Ẹ lọ kíá, ẹ̀yin iranṣẹ ayára-bí-àṣá, ẹ lọ sọ́dọ̀ orílẹ̀-èdè tí ó lágbára, tí ara wọn ń dán, àwọn tí àwọn eniyan tí wọ́n súnmọ́ wọn ati àwọn tí ó jìnnà sí wọn ń bẹ̀rù. Orílẹ̀-èdè tí ó lágbára, tíí sìí máa ń ṣẹgun ọ̀tá, àwọn tí odò la ilẹ̀ wọn kọjá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ti o rán awọn ikọ̀ li ọ̀na okun, ani ninu ọkọ̀ koriko odò, li oju odò, wipe, Lọ, ẹnyin onṣẹ ti o yara kánkan, si orilẹ-ède ti a nà ká ti a si tẹju, si enia ti o ni ibẹ̀ru lati igbayi ati titi lọ; orilẹ-ède ti o ni ipá, ti o si tẹ̀ ni mọlẹ, ilẹ ẹniti odò pupọ̀ pinyà!
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
tí ó rán àwọn ikọ̀ lórí òkun lórí omi nínú ọkọ̀-ọpọ́n tí a fi kóríko ṣe. Ẹ lọ, ẹ̀yin ikọ̀ tí ó yára, sí àwọn ènìyàn gíga tí àwọ̀-ara wọn jọ̀lọ̀, sí àwọn ènìyàn tí a ń bẹ̀rù káàkiri, orílẹ̀ èdè aláfojúdi alájèjì èdè, tí odò pín ilẹ̀ rẹ̀ yẹ́lẹyẹ̀lẹ.